Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 17:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀.

2. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́.

3. Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.

4. Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki.

5. Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú.

6. Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà.

7. Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!”

8. Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 17