Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 14:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́.

2. Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ.

3. Paulu ati Banaba pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, ẹ̀rù kò sì bà wọ́n nítorí wọ́n gbójú lé Oluwa tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ti ọwọ́ wọn ṣe.

4. Ìyapa bẹ́ sáàrin àwọn eniyan ninu ìlú; àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn Juu, àwọn mìíràn fara mọ́ àwọn aposteli.

5. Àwọn Juu ati àwọn tí kì í ṣe Juu pẹlu àwọn ìjòyè wọn dábàá láti ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, wọ́n fẹ́ sọ wọ́n ní òkúta pa.

6. Nígbà tí àwọn aposteli mọ̀, wọ́n sálọ sí Listira ati Dabe, ìlú meji ní Likaonia, ati àwọn agbègbè wọn.

7. Wọ́n bá ń waasu ìyìn rere níbẹ̀.

8. Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí.

9. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá.

10. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 14