Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 13:12-27 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu.

13. Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu.

14. Wọ́n la ilẹ̀ náà kọjá láti Pega títí wọ́n fi dé ìlú Antioku lẹ́bàá ilẹ̀ Pisidia. Wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n bá jókòó.

15. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.”

16. Ni Paulu bá dìde, ó gbé ọwọ́ sókè, ó ní:“Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun wa, ẹ fetí sílẹ̀.

17. Ọlọrun àwọn eniyan yìí, eniyan Israẹli, yan àwọn baba wa. Nígbà tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti bí àlejò, Ọlọrun sọ wọ́n di eniyan ńlá. Ó fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nígbà tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti.

18. Fún nǹkan bí ogoji ọdún ni ó fi ń kẹ́ wọn ní aṣálẹ̀.

19. Orílẹ̀-èdè meje ni ó parẹ́ ní ilẹ̀ Kenaani nítorí tiwọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n jogún ilẹ̀ wọn,

20. fún nǹkan bí irinwo ọdún ó lé aadọta (450).“Lẹ́yìn èyí ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di àkókò wolii Samuẹli.

21. Lẹ́yìn náà wọ́n bèèrè fún ọba; Ọlọrun bá fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó jọba fún ogoji ọdún.

22. Nígbà tí Ọlọrun yọ ọ́ lóyè, ó gbé Dafidi dìde fún wọn bí ọba. Ọlọrun jẹ́rìí sí ìwà rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé, ‘Mo rí i pé Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́, ẹni tí yóo ṣe ohun gbogbo bí mo ti fẹ́.’

23. Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.

24. Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada.

25. Nígbà tí Johanu fẹ́rẹ̀ dópin iṣẹ́ rẹ̀, ó ní, ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kì í ṣe ẹni tí ẹ rò. Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí n kò tó tú okùn bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.’

26. “Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí.

27. Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 13