Lẹ́yìn tí wọ́n ti ka Ìwé Mímọ́, láti inú Ìwé Òfin Mose ati Ìwé àwọn wolii, àwọn olóyè ilé ìpàdé àwọn Juu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin arakunrin, bí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn eniyan, ẹ sọ ọ́.”