Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 9:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí.

6. Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.

7. Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá.

8. Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà.

9. Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata.

10. Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.

Ka pipe ipin Heberu 9