Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 9:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.”

21. Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn.

22. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

23. Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ.

24. Nítorí kì í ṣe àgọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́ ni Kristi wọ̀ lọ, èyí tíí ṣe ẹ̀dà ti àgọ́ tòótọ́. Ṣugbọn ọ̀run gan-an ni ó wọ̀ lọ, nisinsinyii ó wà níwájú Ọlọrun nítorí tiwa.

25. Kì í sìí ṣe pé à-rú-tún-rú ni yóo máa fi ara rẹ̀ rúbọ, bí Olórí Alufaa ti ìdílé Lefi ti máa ń wọ Ibi Mímọ́ jùlọ lọ ní ọdọọdún pẹlu ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.

26. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú.

27. Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn.

28. Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.

Ka pipe ipin Heberu 9