Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 9:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara,

14. mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè.

15. Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé.

16. Nítorí bí eniyan bá ṣe ìwé bí òun ti fẹ́ kí wọ́n pín ogún òun, ìdánilójú kọ́kọ́ gbọdọ̀ wà pé ó ti kú kí ẹnikẹ́ni tó lè mú ìwé náà lò.

17. Ìwé ìpíngún kò wúlò níwọ̀n ìgbà tí ẹni tí ó ṣe é bá wà láàyè. Ó di ìgbà tí ó bá kú.

18. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé pẹlu ẹ̀jẹ̀ ni a fi ṣe majẹmu àkọ́kọ́.

19. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan.

20. A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.”

21. Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn.

Ka pipe ipin Heberu 9