Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 7:12-22 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nítorí bí a bá yí ètò iṣẹ́ alufaa pada, ó níláti jẹ́ pé a yí òfin náà pada.

13. Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú.

14. Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí.

15. Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki,

16. ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò.

17. Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé,“Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae,gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”

18. A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò.

19. Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun.

20. Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra.

21. Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,“Oluwa ti búra,kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ”

22. Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ.

Ka pipe ipin Heberu 7