Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 13:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn.

2. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n.

3. Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà.

4. Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè.

5. Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!”

6. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé,“Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi,ẹ̀rù kò ní bà mí.Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.”

7. Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn.

8. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae.

9. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani.

10. A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀.

11. Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó.

12. Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀.

13. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà.

14. Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀!

15. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Heberu 13