Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 11:25-40 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ.

26. Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú.

27. Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn.

28. Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli.

29. Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi.

30. Nípa igbagbọ ni odi ìlú Jẹriko fi wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti yí i ká fún ọjọ́ meje.

31. Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí.

32. Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii.

33. Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́.

34. Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn.

35. Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú.A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ.

36. A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n.

37. A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira.

38. Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀.

39. Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà.

40. Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà.

Ka pipe ipin Heberu 11