Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 10:34-39 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ.

35. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ.

36. Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe.

37. Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí,“Nítorí láìpẹ́ jọjọ,ẹni tí ń bọ̀ yóo dé,kò ní pẹ́ rárá.

38. Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmiyóo wà láàyè nípa igbagbọ.Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìninú mi kò ní dùn sí i.”

39. Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà.

Ka pipe ipin Heberu 10