Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 1:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

8. Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

9. O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀.Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10. Ó tún sọ pé,“O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa,ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀.Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run.

11. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí.Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ.

12. Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn.Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn.Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà.Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.”

13. Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?”

14. Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.

Ka pipe ipin Heberu 1