Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 3:18-28 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nítorí bí eniyan bá lè di ajogún nípa òfin, a jẹ́ pé kì í tún ṣe ìlérí mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni nípa ìlérí ni Ọlọrun fún Abrahamu ní ogún.

19. Ipò wo wá ni òfin wà? Kí eniyan lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ṣe fi òfin kún ìlérí, títí irú-ọmọ tí ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún yóo fi dé. Láti ọwọ́ àwọn angẹli ni alárinà ti gba òfin.

20. Ètò tí alárinà bá lọ́wọ́ sí ti kúrò ní ti ẹyọ ẹnìkan. Ṣugbọn ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọrun.

21. Ǹjẹ́ òfin wá lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọrun ni bí? Rárá o! Bí ó bá jẹ́ pé òfin tí a fi fúnni lè sọ eniyan di alààyè, eniyan ìbá lè di olódodo nípa òfin.

22. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ohun gbogbo wà ninu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ kí á lè fi ìlérí nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́.

23. Ṣugbọn kí àkókò igbagbọ yìí tó tó, a wà ninu àtìmọ́lé lábẹ́ òfin, a sé wa mọ́ títí di àkókò igbagbọ yìí.

24. Èyí ni pé òfin jẹ́ olùtọ́ wa títí Kristi fi dé, kí á lè dá wa láre nípa igbagbọ.

25. Nígbà tí àkókò igbagbọ ti dé, a kò tún nílò olùtọ́ mọ́.

26. Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.

27. Nítorí gbogbo ẹni tí ó ti ṣe ìrìbọmi nípa igbagbọ ninu Kristi ti gbé Kristi wọ̀.

28. Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu.

Ka pipe ipin Galatia 3