Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 6:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta.

17. Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

18. Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.

19. Ẹ máa gbadura fún èmi gan-an alára, pé kí n lè mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ nígbà tí n óo bá sọ̀rọ̀. Ati pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ tí àwọn eniyan yóo fi mọ àṣírí ìyìn rere

20. tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ.

21. Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa.

22. Ìdí tí mo fi rán an si yín ni pé kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ wa, kí ọkàn yín lè balẹ̀.

23. Kí alaafia ati ìfẹ́ pẹlu igbagbọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu àwọn onigbagbọ.

24. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin.

Ka pipe ipin Efesu 6