Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 5:20-33 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

21. Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi.

22. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín gẹ́gẹ́ bí Oluwa.

23. Nítorí ọkọ ni olórí aya gẹ́gẹ́ bí Kristi ti jẹ́ olórí ìjọ. Kristi sì ni Olùgbàlà ara rẹ̀ tíí ṣe ìjọ.

24. Bí ìjọ ti ń bọ̀wọ̀ fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe sí àwọn ọkọ wọn ninu ohun gbogbo.

25. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.

26. Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.

27. Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí.

28. Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn ọkọ fẹ́ràn àwọn aya wọn, bí wọ́n ti fẹ́ràn ara tiwọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ni ó fẹ́ràn.

29. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó kórìíra ara rẹ̀. Ńṣe ni eniyan máa ń tọ́jú ara rẹ̀, tí ó sì máa ń kẹ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ ni Kristi ń ṣe sí ìjọ.

30. Nítorí ẹ̀yà ara Kristi ni a jẹ́.

31. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, pé, “Nítorí náà ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo darapọ̀ pẹlu aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo wá di ara kan.”

32. Àṣírí ńlá ni èyí. Mò ń sọ nípa ipò tí Kristi wà sí ìjọ.

33. Àkàwé yìí ba yín mu. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níláti fẹ́ràn aya rẹ̀ bí òun tìkararẹ̀. Aya sì níláti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Efesu 5