Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 3:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8. Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.

9. Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́,

10. kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà.

11. Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

12. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ.

13. Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín.

14. Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,

15. tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé.

16. Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun;

17. kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́,

18. kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó;

Ka pipe ipin Efesu 3