Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 3:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìdí rẹ̀ nìyí tí èmi Paulu fi di ẹlẹ́wọ̀n fún Kristi Jesu nítorí ti ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe Juu.

2. Ẹ óo ṣá ti gbọ́ nípa iṣẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ láti ṣe fun yín.

3. Ọlọrun ni ó fi àṣírí yìí hàn mí lójú ìran, gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ọ́ sinu ìwé ní ṣókí tẹ́lẹ̀.

4. Nígbà tí ẹ bá kà á, ẹ óo rí i pé mo ní òye àṣírí Kristi,

5. tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí.

6. Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀.

7. Èyí ni iṣẹ́ tí a fi fún mi nípa ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8. Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.

9. Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́,

10. kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà.

11. Ọlọrun ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ètò rẹ̀, láti ayérayé, tí ó mú ṣẹ ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

12. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ.

13. Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín.

14. Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,

15. tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé.

16. Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun;

17. kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́,

Ka pipe ipin Efesu 3