Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 2:2-8-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nígbà náà ẹ̀ ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni ti ayé yìí, ẹ̀ ń gbọ́ràn sí aláṣẹ àwọn ẹ̀mí tí ó wà ninu òfuurufú lẹ́nu, àwọn ẹ̀mí wọnyi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí ninu àwọn ọmọ tí kò gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu.

3. Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù.

4. Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa,

5. ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là.

6. Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run,

7. kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu.

8-9. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga.

Ka pipe ipin Efesu 2