Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanaya 3:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;yóo láyọ̀ nítorí yín,yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè

18. gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”OLUWA ní:“N óo mú ibi kúrò lórí yín,kí ojú má baà tì yín.

19. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,n óo gba àwọn arọ là,n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògogbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.

20. N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà,nígbà tí mo bá ko yín jọ tán:n óo sọ yín di eniyan patakiati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé,nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín,Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Sefanaya 3