Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanaya 2:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ gbìmọ̀ pọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú.

2. Kí á tó fẹ yín dànù, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ìyàngbò káàkiri, kí ibinu Ọlọrun tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìrúnú OLUWA tó dé ba yín.

3. Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.

4. Àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ìlú Gasa; ìlú Aṣikeloni yóo dahoro; a óo lé àwọn ará ìlú Aṣidodu jáde lọ́sàn-án gangan, a óo sì tú ìlú Ekironi ká.

5. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè Kereti! Ọ̀rọ̀ OLUWA ń ba yín wí, Kenaani, ilẹ̀ àwọn ará Filistia; n óo pa yín run patapata láìku ẹnìkan.

6. Ilẹ̀ etí òkun yóo di pápá oko fún àwọn darandaran, ati ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo ti máa jẹko.

7. Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada.

8. OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè,

9. mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.”

Ka pipe ipin Sefanaya 2