Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 4:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

13. Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké.

14. Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli.

15. Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá.

16. Ọkunrin náà wí fún un pé, “Ojú ogun ni mo ti sá wá lónìí.”Eli bá bi í pé, “Kí ló dé, ọmọ mi?”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 4