Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 31:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun.

2. Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.

3. Ogun náà le fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà ta á ní ọfà, ó sì farapa lọpọlọpọ.

4. Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú.

5. Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 31