Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 30:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná;

2. wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni.

3. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú.

4. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n.

5. Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu.

6. Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.

8. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”

9. Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà.

10. Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.

11. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi,

12. èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn.

13. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.

14. A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 30