Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 28:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí.

19. OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”

20. Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà.

21. Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè.

22. Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.”

23. Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn.

24. Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i.

25. Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 28