Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 26:2-10 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi.

3. Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri,

4. ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀.

5. Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká.

6. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?”Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”

7. Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká.

8. Abiṣai bá sọ fún Dafidi pé, “Ọlọrun ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ ní òní yìí, gbà mí láàyè kí n yọ ọ̀kọ̀, kí n sì gún un ní àgúnpa lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.”

9. Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi.

10. Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 26