27. Nígbà náà ni oníṣẹ́ kan wá sọ fún Saulu pé, “Pada wá kíákíá, nítorí pé àwọn ará Filistia ti gbógun ti ilẹ̀ wa.”
28. Nítorí náà, Saulu pada lẹ́yìn Dafidi, ó sì lọ bá àwọn ará Filistia jà. Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ń pe òkè náà ní Àpáta Àsálà.
29. Láti ibẹ̀, Dafidi lọ farapamọ́ sí Engedi.