Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 21:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”

9. Ahimeleki sì dáhùn pé, “Idà Goliati ará Filistia tí o pa ní àfonífojì Ela nìkan ni ó wà ní ibí. A fi aṣọ kan wé e sí ẹ̀yìn efodu. Bí o bá fẹ́, o lè mú un. Kò sì sí òmíràn níbí lẹ́yìn rẹ̀.”Dafidi dáhùn pé, “Kò sí idà tí ó dàbí rẹ̀, mú un fún mi.”

10. Dafidi sá fún Saulu ní ọjọ́ náà. Ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

11. Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé:‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀,Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

12. Dafidi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ́kàn ó ṣe bí ẹni pé kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ṣugbọn ó bẹ̀rù Akiṣi, ọba Gati gidigidi.

13. Ó yí ìṣe rẹ̀ pada níwájú wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi wèrè. Ó ń fi ọwọ́ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà ààfin, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.

14. Akiṣi bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ kò rí i pé aṣiwèrè ni ọkunrin yìí ni, kí ló dé tí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi?

15. Ṣé n kò ní aṣiwèrè níhìn-ín ni, tí ẹ fi mú un wá siwaju mi kí ó wá ṣe wèrè rẹ̀? Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí ni ó yẹ kí ó wá sinu ilé mi?”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 21