Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 21:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?”

2. Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan.

3. Kí ni ẹ ní lọ́wọ́? Fún mi ní ìṣù burẹdi marun-un tabi ohunkohun tí o bá ní.”

4. Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.”

5. Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?”

6. Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.

7. Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA.

8. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 21