Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Bí ó bá sọ pé kò burú, a jẹ́ wí pé alaafia ni fún iranṣẹ rẹ, ṣugbọn bí ó bá bínú gidigidi, èyí yóo fihàn ọ́ wí pé, ó ní ìpinnu burúkú sí mi.

8. Nítorí náà ṣe èmi iranṣẹ rẹ ní oore kan, nítorí o ti mú mi dá majẹmu mímọ́ pẹlu rẹ. Ṣugbọn bí o bá rí ohun tí ó burú ninu ìwà mi, ìwọ gan-an ni kí o pa mí; má wulẹ̀ fà mí lé baba rẹ lọ́wọ́ láti pa.”

9. Jonatani bá dáhùn wí pé, “Má ṣe ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ṣé mo lè mọ̀ dájú pé baba mi fẹ́ pa ọ́, kí n má sọ fún ọ?”

10. Dafidi bá bèèrè pé, “Báwo ni n óo ṣe mọ̀ bí baba rẹ bá bínú?”

11. Jonatani dáhùn pé, “Máa bọ̀, jẹ́ kí á lọ sinu pápá.” Àwọn mejeeji sì lọ.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20