Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:31-42 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”

32. Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?”

33. Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi.

34. Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.

35. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jonatani mú ọmọde kan lọ́wọ́, ó lọ sí orí pápá gẹ́gẹ́ bí àdéhùn òun ati Dafidi.

36. Ó sọ fún ọmọ náà pé, “Sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo ta wá.” Bí ọmọ náà ti ń sáré lọ, Jonatani ta ọfà siwaju rẹ̀.

37. Nígbà tí ọmọ náà dé ibi tí ọfà náà balẹ̀ sí, Jonatani pè é, ó ní, “Ọfà náà wà níwájú rẹ,”

38. Jonatani tún sọ fún un pe, “Yára má ṣe dúró.” Ọmọ náà ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀,

39. kò mọ nǹkankan; Jonatani ati Dafidi nìkan ni wọ́n mọ ìtumọ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.

40. Jonatani kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ọmọ náà pé kí ó kó wọn lọ sílé.

41. Bí ọmọ náà ti lọ tán, ni Dafidi jáde láti ibi òkúta tí ó sápamọ́ sí, ó sì dojúbolẹ̀, ó tẹríba lẹẹmẹta. Àwọn mejeeji sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọn sọkún títí tí ara Dafidi fi wálẹ̀.

42. Lẹ́yìn náà ni Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí Ọlọrun wà pẹlu rẹ. Kí OLUWA ran àwa mejeeji lọ́wọ́ ati àwọn ọmọ wa, kí á lè pa majẹmu tí ó wà láàrin wa mọ́ laelae.” Lẹ́yìn tí Dafidi lọ, Jonatani pada sí ààrin ìlú.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20