Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:30-35 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ.

31. Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”

32. Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?”

33. Saulu bá ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn, ó fẹ́ pa á. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ dájú pé, baba òun pinnu láti pa Dafidi.

34. Jonatani sì fi ibinu dìde kúrò ní ìdí tabili oúnjẹ, kò sì jẹun ní ọjọ́ náà, tíí ṣe ọjọ́ keji oṣù. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.

35. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jonatani mú ọmọde kan lọ́wọ́, ó lọ sí orí pápá gẹ́gẹ́ bí àdéhùn òun ati Dafidi.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20