Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 20:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi sá kúrò ní Naioti, ní Rama, lọ sọ́dọ̀ Jonatani, ó sì bi í pé, “Kí ni mo ṣe? Ìwà burúkú wo ni mo hù? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ baba rẹ tí ó fi ń wọ́nà láti pa mí?”

2. Jonatani dá a lóhùn pé, “Kí á má rí i, o kò ní kú. Kò sí nǹkankan ti baba mi ń ṣe, bóyá ńlá tabi kékeré, tí kì í sọ fún mi; kò sì tíì sọ èyí fún mi, nítorí náà ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀.”

3. Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 20