Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 19:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ.

5. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu láti pa Goliati, OLUWA sì ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli. Nígbà tí o rí i inú rẹ dùn. Kí ló dé tí o fi ń wá ọ̀nà láti pa Dafidi láìṣẹ̀?”

6. Saulu gbọ́rọ̀ sí Jonatani lẹ́nu, ó sì búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, n kò ní pa á.”

7. Jonatani pe Dafidi ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ó mú Dafidi wá siwaju ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ iranṣẹ fún ọba bíi ti àtẹ̀yìnwá.

8. Ogun tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn Filistini ati Israẹli. Dafidi kọlu àwọn Filistini, ó pa pupọ ninu wọn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini fi sá lójú ogun.

9. Ní ọjọ́ kan, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tún bà lé Saulu, bí ó ti jókòó ninu ilé rẹ̀ tí ó mú ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, tí Dafidi sì ń lu dùùrù níwájú rẹ̀,

10. Saulu ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi mọ́ ògiri, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà wọ ara ògiri, Dafidi bá sá lọ.

11. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, Saulu rán àwọn iranṣẹ kan láti máa ṣọ́ ilé Dafidi kí wọ́n lè pa á ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ṣugbọn Mikali iyawo rẹ̀ sọ fún Dafidi pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, nítorí pé bí o bá di ọ̀la níbí, wọn yóo pa ọ́.”

12. Mikali bá sọ Dafidi kalẹ̀ láti ojú fèrèsé kan, ó sì sá lọ láti fi ara pamọ́.

13. Mikali sì mú ère kan, ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn, ó gbé ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ sibẹ, ó fi ṣe ìrọ̀rí rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.

14. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu dé láti mú Dafidi, Mikali sọ fún wọn pé, “Ara rẹ̀ kò yá.”

15. Saulu tún rán àwọn iranṣẹ náà lọ wo Dafidi, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé e wá fún mi ti òun ti ibùsùn rẹ̀, kí n pa á.”

16. Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà dé, wọ́n bá ère ní orí ibùsùn pẹlu ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ ní ìgbèrí rẹ̀.

17. Saulu sì bèèrè lọ́wọ́ Mikali pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sá àsálà?”Mikali dá Saulu lóhùn pé, “Ó sọ wí pé òun yóo pa mí bí n kò bá jẹ́ kí òun sá lọ.”

18. Dafidi sá àsálà, ó sá lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama, ó sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe sí i fún un. Òun pẹlu Samuẹli sì lọ ń gbé Naioti.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 19