Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 17:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka.

2. Saulu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ibùdó tiwọn sí àfonífojì Ela, wọ́n sì múra ogun de àwọn ọmọ ogun Filistini.

3. Àwọn Filistini dúró lórí òkè ní apá kan, àwọn Israẹli sì dúró lórí òkè ní apá keji. Àfonífojì kan sì wà láàrin wọn.

4. Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.

5. Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli.

6. Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀.

7. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀.

8. Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 17