Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 15:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Saulu bá kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó ka iye wọn ní Telaimu. Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000).

5. Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì.

6. Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki.

7. Saulu ṣẹgun àwọn ará Amaleki láti Hafila títí dé Ṣuri ní ìhà ìlà oòrùn Ijipti.

8. Ó mú Agagi, ọba àwọn ará Amaleki láàyè, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

9. Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run.

10. OLUWA sọ fún Samuẹli pé,

11. “Ó dùn mí pé mo fi Saulu jọba. Ó ti yipada kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa òfin mi mọ́.” Inú bí Samuẹli, ó sì gbadura sí OLUWA ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

12. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ó jáde, ó lọ rí Saulu. Ó gbọ́ pé Saulu ti lọ sí Kamẹli, níbi tí ó ti gbé ọ̀wọ̀n kan kalẹ̀, ní ìrántí ara rẹ̀, ati pé ó ti gba ibẹ̀ lọ sí Giligali.

13. Samuẹli bá lọ sọ́dọ̀ Saulu. Saulu sọ fún un pé, “Kí OLUWA kí ó bukun ọ, Samuẹli, mo ti pa òfin OLUWA mọ́.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 15