Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 15:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “OLUWA rán mi láti fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, eniyan rẹ̀. Nisinsinyii gbọ́ ohun tí OLUWA wí.

2. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo jẹ àwọn ará Amaleki níyà nítorí pé wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti.

3. Lọ gbógun ti àwọn ará Amaleki, kí o sì run gbogbo nǹkan tí wọ́n ní patapata. O kò gbọdọ̀ dá nǹkankan sí, pa gbogbo wọn, atọkunrin, atobinrin; àtàwọn ọmọ kéékèèké; àtàwọn ọmọ ọmú; ati mààlúù, ataguntan, ati ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, gbogbo wọn pátá ni kí o pa.’ ”

4. Saulu bá kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó ka iye wọn ní Telaimu. Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Àwọn tí wọ́n wá láti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000).

5. Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì.

6. Saulu ranṣẹ ìkìlọ̀ kan sí àwọn ará Keni pé, “Ẹ jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki, kí n má baà pa yín run, nítorí pé ẹ̀yin ṣàánú àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.” Àwọn ará Keni bá jáde kúrò láàrin àwọn ará Amaleki.

7. Saulu ṣẹgun àwọn ará Amaleki láti Hafila títí dé Ṣuri ní ìhà ìlà oòrùn Ijipti.

8. Ó mú Agagi, ọba àwọn ará Amaleki láàyè, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

9. Ṣugbọn Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ dá Agagi sí, wọn kò sì pa àwọn tí wọ́n dára jùlọ ninu àwọn aguntan, mààlúù, ati ọ̀dọ́ mààlúù ati ọ̀dọ́ aguntan wọn, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó dára. Wọn kò pa wọ́n run, ṣugbọn wọ́n pa àwọn ohun tí kò níláárí run.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 15