Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 14:49-52 BIBELI MIMỌ (BM)

49. Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali.

50. Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀.

51. Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli.

52. Gbogbo ọjọ́ ayé Saulu ni ó fi bá àwọn ará Filistia jagun kíkankíkan. Nígbà gbogbo tí Saulu bá sì ti rí ọkunrin tí ó jẹ́ alágbára tabi akikanju, a máa fi kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 14