Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 12:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àkókò ìkórè ọkà nìyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? N óo gbadura, OLUWA yóo sì jẹ́ kí ààrá sán, kí òjò sì rọ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ óo mọ̀ pé bíbèèrè tí ẹ bèèrè fún ọba, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ẹ dá sí OLUWA.”

18. Samuẹli bá gbadura, ní ọjọ́ náà gan-an, OLUWA sán ààrá, ó sì rọ òjò. Ẹ̀rù OLUWA ati ti Samuẹli sì ba gbogbo àwọn eniyan náà.

19. Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún wa, kí á má baà kú. Nítorí pé a mọ̀ nisinsinyii pé, yàtọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá tẹ́lẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tún ni bíbèèrè tí a bèèrè fún ọba tún jẹ́ lọ́rùn wa.”

20. Samuẹli dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ẹ ṣe burú, sibẹsibẹ ẹ má ṣe yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹ máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín.

21. Ẹ má tẹ̀lé àwọn oriṣa; ohun asán tí kò lérè, tí kò sì lè gbani ni wọ́n.

22. OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀.

23. Ní tèmi, n kò ní ṣẹ̀, nípa aigbadura sí OLUWA fun yín. N óo sì máa kọ yín ní ohun tí ó dára láti máa ṣe ati ọ̀nà tí ó tọ́ fun yín láti máa rìn.

24. Ẹ máa bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn yín. Ẹ ranti àwọn nǹkan ńláńlá tí ó ti ṣe fun yín.

25. Ṣugbọn bí ẹ bá tún ṣe nǹkan burúkú, yóo pa ẹ̀yin ati ọba yín run.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 12