Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 11:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Saulu pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí ọ̀nà mẹta, wọ́n kọlu ibùdó àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n títí di ọ̀sán ọjọ́ náà. Àwọn tí kò kú lára wọn fọ́nká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí eniyan meji tí wọ́n dúró papọ̀.

12. Àwọn ọmọ Israẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Samuẹli pé, “Níbo ni àwọn tí wọ́n sọ pé kò yẹ kí Saulu jẹ ọba wa wà? Ẹ kó wọn jáde, kí á pa wọ́n.”

13. Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.”

14. Samuẹli wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Giligali, kí á lè túbọ̀ fi ìdí ìjọba Saulu múlẹ̀.”

15. Gbogbo wọn bá pada lọ sí Giligali, wọ́n sì fi Saulu jọba níwájú OLUWA. Wọ́n rú ẹbọ alaafia, Saulu ati àwọn ọmọ Israẹli sì jọ ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 11