Ọkunrin kan wà ninu ẹ̀yà Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikana, ará Ramataimu-sofimu, ní agbègbè olókè Efuraimu. Orúkọ baba rẹ̀ ni Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, láti ìdílé Sufu, ará Efuraimu.