Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 8:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. ó rán Joramu ọmọ rẹ̀ láti kí Dafidi ọba kú oríire, fún ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Hadadeseri, nítorí pé Hadadeseri ti bá Toi jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Joramu mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n fi wúrà ṣe, ati ti fadaka, ati ti idẹ lọ́wọ́ fún Dafidi.

11. Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun;

12. àwọn bíi: àwọn ará Edomu, àwọn ará Moabu, àwọn ará Amoni, àwọn ará Filistia, ati àwọn ará Amaleki; pẹlu ìkógun Hadadeseri, ọba Soba.

13. Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀.

14. Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

15. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo.

16. Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀.

17. Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀.

18. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 8