Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 24:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Inú tún bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ti Dafidi láti kó ìyọnu bá wọn. OLUWA wí fún un pé, lọ ka àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda.

2. Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.”

3. Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?”

4. Ṣugbọn àṣẹ tí ọba pa ni ó borí. Ni Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá jáde kúrò níwájú ọba, wọ́n bá lọ ka àwọn ọmọ Israẹli.

5. Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri.

6. Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni.

7. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.

8. Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 24