Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 23:21-33 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á.

22. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”.

23. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

24. Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu.

25. Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu;

26. Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa;

27. Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa;

28. Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa;

29. Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini;

30. Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi;

31. Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu;

32. Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani;

33. Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari;

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 23