Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 23:20-24 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ.

21. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á.

22. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”.

23. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

24. Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 23