Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 2:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?”Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”

21. Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

22. Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?”

23. Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró.

24. Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni.

25. Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun.

26. Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 2