Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 19:30-42 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.”

31. Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà.

32. Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni.

33. Ọba wí fún un pé, “Bá mi kálọ sí Jerusalẹmu, n óo sì tọ́jú rẹ dáradára.”

34. Ṣugbọn Basilai dáhùn pé, “Ọjọ́ tí ó kù fún mi láyé kò pọ̀ mọ́, kí ni n óo tún máa bá kabiyesi lọ sí Jerusalẹmu fún?

35. Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba.

36. Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni.

37. Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.”

38. Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.”

39. Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀.

40. Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ.

41. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?”

42. Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 19