Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 19:23-32 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.”

24. Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀.

25. Nígbà tí Mẹfiboṣẹti ti Jerusalẹmu dé láti pàdé ọba, ọba bi í pé, “Mẹfiboṣẹti, kí ló dé tí o kò fi bá mi lọ?”

26. Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi.

27. Ó lọ pa irọ́ mọ́ mi lọ́dọ̀ ọba. Ṣugbọn bí angẹli Ọlọrun ni oluwa mi, ọba rí; nítorí náà, ṣe ohun tí ó bá tọ́ sí mi ní ojú rẹ.

28. Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.”

29. Ọba dá a lóhùn pé, “Má wulẹ̀ tún sọ nǹkankan mọ́, mo ti pinnu pé ìwọ ati Siba ni yóo pín gbogbo ogun Saulu.”

30. Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.”

31. Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà.

32. Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 19