Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 18:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000).

8. Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ.

9. Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀.

10. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.

11. Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.”

12. Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára.

13. Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.”

14. Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí.

15. Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa.

16. Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli.

17. Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.

18. Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 18