Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 18:24-33 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀.

25. Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí.

26. Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.”Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”

27. Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.”Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”

28. Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.”

29. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?”Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

30. Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró.

31. Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.”

32. Ọba bi í pé, “Ṣé alaafia ni Absalomu, ọmọ mi wà?”Ará Kuṣi náà dáhùn pé, “Kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Absalomu ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, ati gbogbo àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ.”

33. Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 18