Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 15:10-16 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣugbọn Absalomu rán iṣẹ́ àṣírí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ó ní, “Tí ẹ bá gbọ́ tí wọ́n fọn fèrè, kí ẹ sọ pé, ‘Absalomu ti di ọba ní Heburoni.’ ”

11. Igba ọkunrin ni Absalomu pè, tí wọ́n sì bá a lọ láti Jerusalẹmu. Wọn kò ní èrò ibi lọ́kàn, ní tiwọn, wọn kò sì mọ ohun tí ó wà lọ́kàn Absalomu.

12. Nígbà tí Absalomu ń rúbọ lọ́wọ́, ó ranṣẹ sí ìlú Gilo láti lọ pe Ahitofeli ará Gilo, ọ̀kan ninu àwọn olùdámọ̀ràn Dafidi ọba. Ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i.

13. Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.”

14. Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.”

15. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.”

16. Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 15